Ibadan mesi Ogo, nile Oluyole Ilu Ogunmola, olodogbo keri loju ogun Ilu Ibikunle alagbala jaya-jaya. Ilu Ajayi, o gbori Efon se filafila Ilu Latosa, Aare-ona kakanfo Ibadan Omo ajoro sun Omo a je Igbin yoo,fi ikarahun fo ri mu Ibadan maja-maja bii tojo kin-in-ni Eyi too ja aladuugbo gbogbo logun Ibadan ki ba ni s’ore ai mu ni lo s’ogun Ibadan Kure! Ibadan beere ki o too wo o B’Ibadan ti n gbonile bee lo n gba Ajoji Eleyele lomi ti teru-tomo ‘Layipo n mu Asejire lomi abumu-buwe nile Ibadan A ki waye ka maa larun kan lara, Ija igboro larun Ibadan
Praise & Anthem
Oriki (Praise Poetry) Ibadan
Ibadan Anthem
Ibadan Ilu Ori oke Ilu Ibukun Oluwa K"Oluwase o nibukun Fun Onile at"Alejo Egbe; Eho e yo ke si gberin Ogo f"Olorun wa lo"orun Ibukun ti Obangiji Wa pelu re wo Ibadan Mo wo lati ori oke Bi ewa re ti dara to B"odore kotile dara Sibe o la ibadan ja Egbe; Eho e yo ke si gberin Ibadan Ilu ori oke K"Oluwa se o nibukun Ki gbogbo joye inu re Je elemi gigun fun wa Egbe;Eho e yo ke si gberin Ibadan Ilu to ngbajeji Tiko si gbagbe omore kife ara ko wa sibe Fun Onile at"Alejo Egbe;Eho e yo ke si gberin Ibadan ilu Jagunjagun Awonto so o dilu nla Awa omo re ko ni je K"ola ti ogo won run Egbe; Eho e yo ke si gberin